Home | Outreach | Articles | Services | Personal Development | Poems | Events | Others

D’KINGZ Pen is media organization that is motivated by the desire to impact and influence the society positively through various media platforms. more info: Email: dkingzpen@yahoo.com Whatsapp: +2348036524707 Twitter @Dkingzpen IG:@Dkingzpen

Friday, September 30, 2011

Orisun Oruko

Oruko re po oluwa
Oye re po kabiyesi
Ko si ohun t’a le fi o we eleda
Mo wo kiri, mi o ri eni bi re afigbogbo ara s’oju
Oye re poju, ko l’ounka.

Ibeere ati opin ohun gbogbo
Orison aye ohun orun
Eleda ohun gbogbo, eyi ti a ri ati eyi ti a ko ri
Ouwa awon oluwa, eni ti a kori t’ o n ri wa
Orison gbogbo ogbon ati oye.

Atof’arati, eni ti a nfi gbgbo ara le
Gbani gbani, eni t’o ti gba wa
Olufini mo ona, eni t’o n to wa s’ona
Oluranlowo eda, eni ti o nran ni lowo
Eletilukara bi ajere, ko si ohun t’a n wi ti e o gbo

Arugbo ojo, oba ti ki n sa
Arugbo ojo, oba ti ki n baje
Arugbo ojo, oba ti ki n tan
Arugbo ojo, oba t’o wa lati ibeere
Arugbo ojo, oba ti a ko le ro loye
Titi aye ni oruko re oba mi
Titi aye ni oruko re yoo ma kan
Titi aye ni yin oluwa mi
Oba oke, oba ile, oba ohun gbogbo
Titi li a o ma kan sara si o.

A ko le yin o tan
A ko le ki o tan
A ko le mo o tan
A ko le ri o tan
Oba ti ko le tan.

Otun otun ni o baba mi
Orisun mi o, eyi ti ko ni opin
Eewa ti ko le san i o, orisun eewa
Awamarididi ni o baba, tani eni to le ri’di re?
Mo wa kiriri, mow o kiri, ko si.

Iwo ni oluko
Iwo ni olumo
Iwo ni olulana
Iwo ohun gbogbo
Awama rirdi ni o baba mi.

No comments:

Post a Comment